In Christian communities, Bible study is the study of the Bible by ordinary people as a personal religious or spiritual practice. |
láàárín àwùjọ Kristẹni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jé kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti àwọn gbáàtúù èèyàn n se gege bi irú ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe tabi asa Isin. |
Some denominations may call this devotion or devotional acts; however in other denominations devotion has other meanings. |
àwọn ẹ̀sìn kan a maa pe eleyii ni ìfọkànsin tabi ọ̀ràn ìfọkànsìn: Àmọ́ nínú àwọn ìjọ mìíràn ìfọkànsin ni nítumọ̀ mìíràn |
Bible study in this sense is distinct from biblical studies, which is a formal academic discipline. |
ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́nà yìí jẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.si ẹ́kọ̀ọ Bíbélì, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀kà ẹ̀kọ́ kíkọ́ gbogbo gbòò |
In Evangelical Protestantism, the time set aside to engage in personal Bible study and prayer is sometimes informally called a Quiet Time. |
nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere ti Pùròtẹ́sítáǹtì, àkókò áti ìgbà tí a yà sọ́tọ̀ láti lọ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà ni a sábà máa ń pè ní àkókò pípa rọ́rọ́ lona ìgbafẹ́ |
In other traditions personal Bible study is referred to as "devotions". |
nínú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ mìíràn wọ́n ń pe e ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìfọkànsin |
Catholic devotions and Anglican devotions both employ the Lectio Divina method of Bible reading. |
àwọn ìfọkànsìn àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì àti ìfọkànsìn àwọn ọmọ ìjọ Áńgílíkà jọ ń lò Ọ̀nà kíka àtọ̀runwá fún kíka Bíbélì |
Christians of all denominations may use Study Bibles and Bible Reading notes to assist them in their personal Bible studies. |
gbogbo àwọn ìjọ Kristẹni lè lo Bibeli Atọ́ka àti Ìwé àlàyé Bíbélì láti ṣèrànwọ́ fún wọn nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn |
However, the use of such aids is discouraged in many churches, which advocate the simple reading of Bible passages. |
Àmọ́, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì a ma a kede jíjáwọ́ nínú ṣíṣàmúlò irú nǹkan bẹ́ẹ̀, wọ́n ń wàásù pé kí a ma a ka ẹsẹ Bíbélì ni rọrùn |
In some cases, the practice of reading through the entire Bible in a year is followed, this usually requires readings each day from both the Old and New Testament. |
Nígbà míì, àwọn ìṣe kika odindi Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin lọ́dọọdún, Èyí sábà máa ń béèrè pé kí a kà láti inú Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun lójoojúmọ́ |
This practice, however, has been widely criticised on the basis that the understanding gained of each specific passage is too vague. |
Àmọ́, Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bẹnu àtẹ́ lu àṣà yìí lọ́lá pé òye tí a jèrè látinú ibì ẹsẹ kan pàtó kì í tiẹ̀ yé èèyàn rárá |
The association of Bible study and prayer is an important one. |
ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà ṣe pàtàkì gan-an |
Christians do not merely study the Bible as an academic discipline, but with the desire to know God better. |
àwọn Kristẹni kì í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kà ẹ̀kọ́ kíkọ́ lásán ṣùgbọ́n pẹ̀lú fífẹ́ láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáradára si |
Therefore, they frequently pray that God will give them understanding of the passage being studied. |
Nítorí náà wọ́n n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run á fún wọn ni óye àwọn ẹsẹ tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lóòrèkóòrè |
They also consider it necessary to consider what they read with an attitude of respect, rather than the critical attitude which is frequently followed in formal study. |
Wọ́n tún kà á sí eyi ti o pọn dandan pe ki won fi ìwà ọ̀wọ̀ wo ohun tí wọn kà dípò iwa bibẹnu àtẹ́ lu ti àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nínú ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì |
To them, the Bible is not just a sacred book, but is the very Word of God, that is, a message from God which has direct relevance to their daily lives. |
sì wọ́n, Bíbélì kì íṣe ìwé mímọ́ọ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kìkì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, ìyẹn ni pé, iṣẹ́ tabi ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run èyí ti ó ṣe pàtàkì ní tààràtà sì ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́
|