What is “governance”? |
Kíni "ìṣèjọba"? |
The term governance often gives rise to confusion because it is (erroneously) assumed that it must refer solely to acts or duties of the government. |
Ọ̀rọ̀ náà ìṣèjọba máa ń rújú nítorí a máa n rò (tí kó rí bè) pe ó gbọdọ̀ tóka nìkan sí àwọn ìṣẹ́ tàbí àwon ojúṣe ìjọba. |
Of course, governments do play an important role in many kinds of governance. |
Lóòótó, àwọn ìjọba maá n kó ipa pàtàkì ní àwọn oríṣi ìjọba púpọ̀. |
However, in fact, the concept is far broader, and extends beyond merely the State. |
Síbẹ̀síbẹ̀, ní pàtó, ọ̀rọ̀ náà gbòrò gan, ó sì ní ṣe ju Ìpínlẹ̀ nìkan lọ. |
For example, we have seen increasing reference recently to the notion of “corporate governance”, a process that involves oversight both by the State and by a host of non-State bodies, including corporations themselves. |
Fún àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí, a ti rí ìtọ́kasí tó pọ̀ọ̀ sí èrò o "ìṣèjọba alájùmọ̀ṣe", ìlànà kan tí ó níse pẹ̀lú àbójútó láti Ìpínlẹ̀ náà àti ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ẹgbẹ́ tí kì í ṣe ti Ìpínlẹ̀, pẹẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ fúnrarawọn. |
Don McLean points out that the word governance derives from the Latin word “gubernare”, which refers to the action of steering a ship. |
Don McLean tọ́ka pé ọ̀rọ̀ náà ìṣèjọba jáde láti ọ̀rọ̀ Latin náà "gubernare", tí ó túmọ̀ sí ìgbésẹ̀ wíwa ọkọ̀ ojú omi.
|
This etymology suggests a broader definition for governance. |
Orísun yìí fi ìtumọ̀ tó gbòrò hàn fún ìṣjọba. |
One important implication of this broader view is that governance includes multiple tools and mechanisms. |
Ìtumọ̀ pàtàkì kan ti ìwòye gbòrò yí ni wípé ìṣèjọba níṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irinṣẹ́ àti àkójọpọ̀ ètò. |
Traditional law and policy are certainly among those mechanisms. |
Òfin àti ìlànà ìṣe ìbílẹ̀ wà dájúdájú lára àwọn àkójọpọ̀ ètò náà. |
However, as we shall see throughout this primer, governance can take place through many other channels. |
Síbẹ̀síbẹ̀, bí a ó ti ṣe rí ní gbogbo ìfáàrà yí, ìṣèjọba lè wáyé ní oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà míì. |
Technology, social norms, decision-making procedures, and institutional design: all of these are as equally important in governance as law or policy. |
Ìmọ̀ ẹ̀rọ, àwọn àṣà àwùjọ, àwọn ìlànà ìpinnu ṣíṣẹ, àti ètò tó ní ìgbékalẹ̀: gbogbo àwọn ǹkan wọ̀nyí náà ló ṣe pàtàkì nínú ìṣèjọba bíi ti òfin àti ìlànà ìse. |